Tuesday, 21 February 2017

Alo apamo (Alo o! Aloo!!)

Osupa to yo loke yii mumi ranti igba ewe.Oma se o. Awon omo ode oni kole mon ohun ti er osupa je tabi iwulo ati imulo alo pipa. Alo kii se fun ere lansan. O ma n koni leko asi maa lani loye pelu. hmmm, igba kan o lo bii orere. Be si ni ogun omode kole sere f'ogun odun. awon apeere alo apamo nbe funyin nisale.

Q: A un lo, o k'oju siwa, a un bo, o k'oju siwa      
Ans: Ilu gan-gan
Q: Adaba kekeluwon, ko s'oja ti kii na
Ans: Owo
Q: Akuko Baba mi la e la e, akuko Baba mi la e la e, owo ni nje, kii j'agbado
Ans: Ile Ejo
Q: Aso Baba mi la e la e, aso Baba mi la e la e, eti ni ti n gbo, kii gbo laarin
Ans: Odo
Q: Awe obi kan, aje d'Oyo
Ans: Ahon
Q: Bi ile gbajumo ti dara to , ko l'oju
Ans: Eyin
Q: Birikila eti'do, asise ma gb'owo
Ans: Akan
Q: Gbogbo ile sun, kanmbo osun
Ans: Imu
Q: Gele dudu gbaja ona
Ans: Eerun
Q: Igi Baba mi la e, la e, Igi Baba mi la e, la e, ori lati n gun de idi
Ans: Koto

95 comments:

  1. Opo baba mi kan laelae,opo baba mi kan laelae,ojo toba ti wo aso pupa lo raye mo,talo mo o?

    ReplyDelete
  2. Ko lapa ko lese o be si gbo o pii
    Kini o ?

    ReplyDelete
  3. oruku tindin tindi oruku tindin tindi oruku ro igba aso ko kan le, kinni oo

    ReplyDelete
  4. Kilo koja niwaju ile oba to ko ki oba?

    ReplyDelete
    Replies
    1. agbara ojo. Sugbon bi a ba ni ki a woo daada, nkan po to le wuwa bi agbara bii, eefi, esinsin, ategun, ati ohun gbogbo ti kii se eyan tabi ohun ajoji.

      Delete
  5. A ran omo lakara,akara de let saaju omo. Ki Ni o?

    ReplyDelete
  6. Won ni ki n mu wa, Mo mu wa, won ni kin daa pada n ko Mo ibe mo o kini o?

    ReplyDelete
  7. Mo duro owo mi ko to mo bere owo mi ko to kini o?

    ReplyDelete
  8. Mo jee jee mo kan eegun, mo tun jee kee, mo kan ara eran. Kini o?

    ReplyDelete
  9. Eniyan n gunyan aja njo. Kini o

    ReplyDelete
  10. Omo buruku woja oja tu.
    Kini oooo

    ReplyDelete
  11. Enter your comment...agutan dudu de odo,o di funfun o

    ReplyDelete
  12. Opo baba mi laelae, opo baba mi laelae, ojo to ba de fila pupa Ni iku de ba.
    Kinni o

    ReplyDelete
  13. Onlo oro funfun onbo oro pupa kini o

    ReplyDelete
  14. Onlo oro funfun onbo oro pupa.
    Kini o.

    ReplyDelete
  15. Igi buruku koja sigbo solum

    ReplyDelete
  16. Alo o, alo o, abi Omo lojo o n gbeja iya re! Kinni o

    ReplyDelete
  17. Alo o, alo, kosemi koromi, mo kan ni Iko! Kinni o?

    ReplyDelete
  18. Agba meta lo sode marun lo pada bo wale ki ni o?

    ReplyDelete
  19. Ewura gedegbe a bu u titi ko ni oju ki ni o?

    ReplyDelete
  20. A bi omo ni oojo o n gbeja iya re ki ni o?

    ReplyDelete
  21. O loyun won sa fuu o bimo won yo no mini o

    ReplyDelete
  22. Aji tuu maa ka eni
    A we tan ma kun osun
    Oji kutu ponmi eeru
    Meta la a pa a si meta lu a
    Mo o n o
    Kin ni o ?

    ReplyDelete
  23. Adie dudu bimo funfun gbaa wo,kini o

    ReplyDelete
  24. Mo yabge rabata mo fi ewe rabata no mini o

    ReplyDelete
    Replies
    1. Ayé ati òrun ni, sugbon oò ko àló yen dáadáa

      Delete
  25. Eyin Omo Yooba, e ku ise opolo o. Mo n gbadun yin lori ikanni yii o

    ReplyDelete
  26. Alo oo, A belekun sunkun, elekun dake oun o dake mo kinni oo?

    ReplyDelete
    Replies
    1. Kurukuru ojo tòun kan tí òjò. Ba dáa tán ni oo

      Delete
  27. Onítèmí òkè òun. Òní òun nifemi gbogbo òun timo bá ti fe lòun bamise. Kini óò??

    ReplyDelete
  28. Irínwó ni ọmọ tòun bẹ nínú atare, egebfa ni ti ọmọ àgbàdo, ìyá kan nbẹ ọmọ méjìlá ni ohun bí. Kínní??

    ReplyDelete
  29. Esin idi iroko Ajo Omo jo iya, kin ni oo

    ReplyDelete