Tuesday 21 February 2017

Alo apamo (Alo o! Aloo!!)

Osupa to yo loke yii mumi ranti igba ewe.Oma se o. Awon omo ode oni kole mon ohun ti er osupa je tabi iwulo ati imulo alo pipa. Alo kii se fun ere lansan. O ma n koni leko asi maa lani loye pelu. hmmm, igba kan o lo bii orere. Be si ni ogun omode kole sere f'ogun odun. awon apeere alo apamo nbe funyin nisale.

Q: A un lo, o k'oju siwa, a un bo, o k'oju siwa      
Ans: Ilu gan-gan
Q: Adaba kekeluwon, ko s'oja ti kii na
Ans: Owo
Q: Akuko Baba mi la e la e, akuko Baba mi la e la e, owo ni nje, kii j'agbado
Ans: Ile Ejo
Q: Aso Baba mi la e la e, aso Baba mi la e la e, eti ni ti n gbo, kii gbo laarin
Ans: Odo
Q: Awe obi kan, aje d'Oyo
Ans: Ahon
Q: Bi ile gbajumo ti dara to , ko l'oju
Ans: Eyin
Q: Birikila eti'do, asise ma gb'owo
Ans: Akan
Q: Gbogbo ile sun, kanmbo osun
Ans: Imu
Q: Gele dudu gbaja ona
Ans: Eerun
Q: Igi Baba mi la e, la e, Igi Baba mi la e, la e, ori lati n gun de idi
Ans: Koto

Thursday 16 February 2017

Do you know what simile is in Yoruba?

SIMILE APA KININ

Yoruba is such a beautiful language which is quite dynamic in it's own way. Could remember those times when my father will always compare any object or situation with something else. then I do wonder what the similarities were if any. It dawn on me when I understand figure of speech in English. Below examples are popular among lots that grew up hearing.
1. O  dudu bii koro eedu
As black as charcoal
2. O buru bii ekun
As wild as a lion
3. O dara bi egbin
As pretty as a damsel
4. O d'ojuru bii ese telo
As scattered as tailor's feet
5.O dun bii oyin
As sweet as honey
6. O duro bii igi
As still as a tree
7. O funfun bii l'ekeleke
As white as cattle egret bird
8. O gaa bii ope
As tall as a palm tree
9. O gbon bii opele
As wise as an oracle
10. O jina bi orun
As far as heaven
11. O kere bii ina gun
As small as fire a fly
12. O koro bii ewuro
As bitter as bitter leaf
13. O mọlẹ bi orun
As bright as the sun
14. O n faa bii igbin
As sluggish as a snail
15. O n fo bi ẹyẹ
It's flying like a bird

Anpara po loro Yoruba, so don't get it twisted.

Yoruba people likes anpara so much that no sentence is complete without on. Se ele imagine wipe kosi ara tabi esi tikoni answer. And do you know why? Because won expect ki awon eeyan ni common sense and Yoruba kii fii gbogbo enu soro. Oro die pelu thought process niyi toku..
















For example
Salutation: Eku ile ma
Response:Tinba kuule nko?
Q: Say where should I put it?
A: Gbe elemi l’ori (which you dare not)
Q: Were you calling me?
A: hmmhmm, eni keji e nimonpe
Q: #500? Can I have it for #350?
A: Oti. E bama sanwo rara
Q: Can 2 have one please?
A: Rara, gbogbo e ni kogbe
Q: Can I enter
A: Sun sita
Q: Ta lo wa nibeyen
A: Tanlatakusi alata rodo ni
Q: Did the lecturer later show up?
A: Abo ti wa ni (this line is still trending)
Q: Se ile yin niyen?
A: hmhmmm. Ile yin ni
Son: I am going to my friend’s house, I’ll be back by 7pm
Mum: Kuku maa gbe be!
Therefore, if you expect a typical Yoruba to spoon feed you every details of you discuss. Ohun ti oju re bari tabi ti eti re bagbo. Ko fafamonni o. As Owe Yoruba dictate “Oro abo la nso f’omoluwabi, toba denu e, adi odidi”.


Wednesday 15 February 2017

Report card conversation

Conversation between a Yoruba and his son who just brought his report card home.
Father: so you came second abi?
Son: yes sir (happily)
Father: kilo n dun e ninu?
Son: (silence)
Father: kilode to gbe 1st?
Son: (silence)
Father: heheen? Se eni to gbe 1st l’orimeji nii? (Does the best student have 2 heads?)
Son: rara (no)
Father: abi class kan naa ko lewa?
Son: (dumbfounded)
Father: Ori ori e, olodo osi. Ko mo ju ounje lo.Iya re lojo. (You are so dull and doesn’t know more than eating. You definitely takes after your mum)

Oh my! Nigeria papas really know how to kill joy jare. They may even claim they were the best throughout their academic life.

Simple tricky question



Most popular snub line in Yoruba


Funny Yoruba question


31 suffix frequently used in Yoruba homes

Yoruba people wa lara eya to funny ju😂
Won ni afiwe ti ko ni rival pelu ara orisirisi.
Can you imagine wipe kosi ona ti eeyan legba ma jẹbi ọrọ especially if you are the younger one.

1.  Se oro ataaro lo n kesi? Arindin2.    Se o monyan ki ni? Alaileko
3.    Ta lo gbe enu e soro? Amẹbọ
4.    Se won bi e? Olofofo
5.    Da pada fun omo yen joo. Agbaya
6.    And you left him behind all alone? Ọdaju
7.    Why do you finish it all? Onijekujẹ
8.    Mo ti n pe e lataaro. Eleti ikun
9.    Brown ni moni koo gbe not blue. Alagbọya
10.  Stop talking. Alabẹbẹ
11.  Ni bo ni traffick wa? Onirinkurin
12.  Lo we joo. Oloorun
13.  Can’t you lift that small bag? Ọlẹ
14.  (After two call out) O n kami l’ohun abi
15.  You won’t remembaa. Alakogbagbe
16.  Put it down. Ọde
17.  #200 for snacks? Onijekuje
18.  Stop stepping on that bowl now. Apa
19.  Stop pinching that doy. Ika
20.   Is that what I sent you?. Oponu
21.  But you’ve just eaten. Tifun lọran
22.  And you are hungry again, olonje iya
23.  Don’t carry it like that now, Basejẹ
24.  O tii wẹlataa rọ! Ọbun
25.  You don’t know 8-5. Olodo
26.  You are too stubborn. Alagidi osi
27.  You been playing game since. Ko mọ jere lọ.
28.  Won’t you return it? Abunu
29.  Is it me you’re doing that too? Onibaje
30.  Leave me jọọ. Alainisẹ
31.  You are so funny. Oniyẹyẹ

Monday 13 February 2017

Learn more Yoruba proverbs

YOU SHOULD BE ASHAMED OF YOURSELF

That is what you'll hear from an elderly Yoruba person while reprimanding someone who is feuding with a younger fellow or someone not of their league. The beauty of proverb is that you don't have to hit the nail on the head directly but rather address the issue wisely or should I say codedly.
For example, let's say two kids are dragging a toy which neither is ready to let go of, the mum on this occasion will face the older one and say
 "ADIYE FUNFUN KO MORARA L'AGBA". Literally, an old roaster doesn't know it's worth. Which means it's not expected of an elder to be fighting over such item with a younger fellow. 
In short, you don't know your worth.

Wednesday 8 February 2017

Enemy koni rest

Enemy ni won npe lota
Ota ni eni ti kofere fun eyan
Ota ama wa ona ati double cross
Ama a se won bii bad bad fun eyan
Tabi ki won ma lepa eni fun idi kan or meji
Won kii ro ire koyan rara
Ota ma wicked oo, ota buru
In fact, won tun le maa gbèrò wípékí ènìyàn roka koma wa obe kiri.
Tabi eniyan tie sun komajimo lo ma nse won.

OLORUN MA FIWA F'OTA YO
ELEDUMARE KONI FIWA F'OTA MU.
MA JEKI OMO ARAYE O RIDI MIO!!!!!!

Who sabi eleyi?

                      MASOWO MA JERE

- MASOWO MA JERE
- MA JERE OHUN TO MOBA FOWO MISE..
- MASOWO MA JERE
- MA JERE OHUN TI MOBA FOWO MISE
- OPO EDA WO LOLE SAMI ADURA YEN
- AMON NITEMI, MOSAMI ADURA MO        GBETO ADURA MI
- ERE LOMO OLOJA NJE O, TOBADALE
- ERE LOBINRIN N JE LABO OJAA
- MAJERE, MAJERE OHUN TI MOBA FOWOMISE
-MAJERE OO. by K.S.A

Right thing is what you're doing and you want people to know of while wrong is what you want no-one to know not.

Nje ise ati ise omoluwabi le toniloju bi?

Sami adura yii

It is well


 Oro mi kòní su Olorun Iwo nko?

Gbakoso Olorun mi

Ebi Liu we ore ara.  Iya kii somi obe. May I never go hungry Olorunmi.

Adura lo le şe. Prayer can do it


Fact meji (2) lori pepeye

ALAYE BABA ORO

1- Bi pepeye ba je okuta omi nio fi su.
Eeyan le lo oro tabi owe yii bi iwure, adúrà, ré ibi dànù tàbí kí ènìyàn go jeje.
Bì àpęęrę; bí ęlòmìràn bà ń gbèrò aburú sì èyàn, alò wípé "ìpinu yín kòní sę lórí no nítorípé bí pępęyę bá ję òkúta, omi ni too fisu".

Oranmileti orin Baba Kayode Fashola to lo bayii
Bi pepeye ba jokuta, omi nio fisu
Iponri aja kogbodo bekun ni buba.
That is to say, lako mowa bii ibon😐😃

2- Iwaju ni pepeye n ko omo re si.
Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister korin wípé:
Iwaju ni pepeye n gba komosii
Gbogbo igba ta o bati se ibaje araye
Iwaju la o  ma wa lojokojo
Eyin, eyin lomo adiye to'yae
'diye nto yare o
E o ma to leyinwa
To leyinwa oo
E o ma to leyinwa.

Igbagbo wanipe akajuwe towa loke yii ti salaye oro yi ni şoki ati ni kunkun.
Mo rii yín naa.....

Sunday 5 February 2017

Adura to le wo mountain.


ADURA SE KOKO
ADURA SE PATAKI
ADURA LO N GBA
KII SE AGBARA.


















20 Owe Yoruba to make sense.



Owe l'esin oro
Oro l'esin owe
Boro ba sonu
Owe laa fi nwa.....😊

1. A kìí bá ara eni tan ká fara eni nítan ya

2. A kii f'omo aparo s'abe j'oka

3. A kii gbo kuku ojo, k'ada omi inu agbada nu

4. A kii jaye Oba, kasu 'ara

5. A kii leni ni musan ka mu kikan

6. A kii n'igil'ogba, ka ma mon eeso re

7. A kii so'osa l'odo kii labelabe o mamon

8. A koni binu ori titi, kafi fila dedi

9. A n beru aja, alaja sebi oun la’nberu

10. A n buni nje a n buni, afini han nje afini han, ewo ni e nle oo ara Ibadan lo l'ojude

 Ogunmola.

11. A n gee l'owo, o tun boruka

12. A n je ekuru kotan, etungbon owo re sawo

13. A n kii, a n sa, oniwon j’oun o joye Baba un

14. A nwa ore kun ore ni,akii wa ota kun ota

15. Aatan ti o ba gba egbin, koni kun boro

16. Ababa kii ku sugbe, igida, eye fo lo

17. Abere toba ni okun nidi, koni sonu

18. Abo oro la nso f'omoluwabi, bo ba de nu re, a d'odidi

19. Adaba tunramu, odo n gbarere lo

20. Adaba tunramu, odo n gbarere lo

Ni soki l'obe oge. A o fi adagba eto ko sibiyi titi di igbamiran ti a o tun ko awon owe miran
pelu itumore pelu.

Layo oo.....



Owe. Yoruba proverbs

                                                        


                                                               OWE L'ESIN ORO....
Owe means Yoruba proverb.

Use. (Imulo)
For advice (imoran)
For message (aroko)
For suggestion (igbani niyanju)
For warning (fun ikilo)
To buttress a fact (lati fi te oro nidi)
E.t.c (abbl).

Find below some examples of Yoruba proverbs














Yorubadun logos


OLORIRE DAA?
AWA RE O OMO YORUBA
OLORIIRE DA?
AWA RE O YORUBA
OMO ARISE?
OMO ARISE LAWA NJE.....
design:marvymalbak

design:marvymalbak

design:marvymalbak














Yorubadun

Ekaabo.
A o ma lo oju opo yii latii maa gbe ede, asa, ewa, odun, eto ati ogo ede yoruba laruge.

Gegebi a se riisi wipe ede yoruba ati pupo ninu asa ati ise wa ko fi gbogbo ara munadoko bii tateyin wa. Paapajulo lawu ati laarin awon ogo were iwoyi.
 Aanu ara misemi pupo nigba ti moni kii omo mi kaa eko ede youba anpe kan ti o sii beere si ni kalolo. Sugbon mio rii bawi oo. Niwon igba tojewipe ede geesi lo n gbo nibi gbogbo botilejepe Yoruba ni a n so nilewa. Nigbati mo ke gbanjare ni mo wa se akiyesi wipe "AISAN TO N SE ABOYADE" loro yii, "GBOGBO OLOYE LO NSE".

Fun idi eyi, a o ma fii agbede yii gbarawa niyanju nipa oun gbogbo to romo ede Yoruba.

Emaa bawa kalo o.