Owe l'esin oro
Oro l'esin owe
Boro ba sonu
Owe laa fi nwa.....😊
1. A kìí bá ara eni tan ká fara eni nítan ya
2. A kii f'omo aparo s'abe j'oka
3. A kii gbo kuku ojo, k'ada omi inu agbada nu
4. A kii jaye Oba, kasu 'ara
5. A kii leni ni musan ka mu kikan
6. A kii n'igil'ogba, ka ma mon eeso re
7. A kii so'osa l'odo kii labelabe o mamon
8. A koni binu ori titi, kafi fila dedi
9. A n beru aja, alaja sebi oun la’nberu
10. A n buni nje a n buni, afini han nje afini han, ewo ni e nle oo ara Ibadan lo l'ojude
Ogunmola.
11. A n gee l'owo, o tun boruka
12. A n je ekuru kotan, etungbon owo re sawo
13. A n kii, a n sa, oniwon j’oun o joye Baba un
14. A nwa ore kun ore ni,akii wa ota kun ota
15. Aatan ti o ba gba egbin, koni kun boro
16. Ababa kii ku sugbe, igida, eye fo lo
17. Abere toba ni okun nidi, koni sonu
18. Abo oro la nso f'omoluwabi, bo ba de nu re, a d'odidi
19. Adaba tunramu, odo n gbarere lo
20. Adaba tunramu, odo n gbarere lo
Ni soki l'obe oge. A o fi adagba eto ko sibiyi titi di igbamiran ti a o tun ko awon owe miran
pelu itumore pelu.
Layo oo.....